Posts

Featured post

KRIST' KI 'JOBA RE DE

Words: Lewis Hensley, 1867 Music: St. Cecilia, Kingsland Krist' ki 'joba Re de, Ki ase Re bere; F' opa-rin Re fo Gbogbo ipa ese. Ijoba ife da, Ati t' Alafia? Gbawo ni irira Yio tan bi t'orun? Akoko na ha da, T' ote yio pari, Ika at' ireje, Pelu ifekufe? Oluwa joo, dide, Wa n'nu agbara Re; Fi ayo fun awa Ti o nsaferi Re Eda ngan ooko Re, 'Koko nje agbo Re; Iwa 'tiju pupo Nfihan pe 'fe tutu. Ookun bole sibe, Ni ile keferi: Dide 'Rawo ooro, Dide, mase wo mo. Amin. Source: Yoruba Baptist Hymnal #149 English Thy kingdom come, O God! Thy rule, O Christ begin! Break with thine iron rod the tyrannies of sin! Where is thy reign of peace, and purity and love? When shall all hatred cease, as in the realms above? When comes the promised time that war shall be no more, oppression, lust, and crime shall flee thy face before? We pray thee, Lord, arise, and come in thy great might; revive our lon...

'Bi 'Sadi Nla L'Olorun Wa / A Mighty Fortress is Our God

Author: Martin Luther (1529) 'Bi'sadi nla l'Ọlọrun wa, Odi wa ti ko le yẹ;  Olùrànlọ́wọ́ n'nu igbi,  Idanwo to yi wa ka  'Tori ọta 'gba nni, Tun fẹ ṣe wa n'ibi;  Agbara re si pọ, Pẹlu ikorira,  Ko s'iru rẹ ni aye yi. A ko gbẹkẹl' agbara wa,  Tori yo ja wa kulẹ  Ti ko ba si pe Ẹni naa, Ti Ọlọrun yan fun wa  O fẹ m'Ẹni naa bi?  Jesu Kristi ni iṣe  Oluwa Ologun,  Ẹni ayeraye,  Yoo si ṣẹgun ni dandan. B'ẹmi aimọ ni gbogb'aye,  N halẹ lati bo wa mọlẹ; A ki o bẹru 'tor'Ọlọrun  Fẹ ṣẹgun nípasẹ̀ wa;  Ọm' alade okunkun,  Ẹ̀rù rẹ̀ ko ba wa A o bori 'runu rẹ Iparun rẹ daju Ọr' Ọlọ́run yoo bii ṣubu Ọrọ yẹn ju agbara aye lọ,  Ṣíọ̀ sí wọn, o wa titi, Ẹ̀mí at' awọn ẹ̀bùn Rẹ̀  Jẹ tiwa nipasẹ Jesu. Ẹrù, ará lè lọ, At' ara kiku yìí  Won le pa ara yìí: Oot' Ọlọ́run sì wà Ìjọba Rẹ̀ wà títí láí.  Source: Hymnaro #703 (Some adjustments made in the translation by me, Ayobami Temitope Keh...

B’ORUKO JESU TI DUN TO / HOW SWEET THE NAME OF JESUS SOUNDS

Author: John Newton 1. B’oruko Jesu ti dun to, Ogo ni fun Oruko Re o tan banuje at’ogbe Ogo ni fun oruko Re Ogo f’oko Re, ogo f’oko Re Ogo f’oruko Oluwa Ogo f’oko Re, ogo f’oko Re Ogo f’oruko Oluwa 2. O wo okan to gb’ogbe san Ogo ni fun oruko Re Ounje ni f’okan t’ebi npa Ogo ni fun oruko Re 3. O tan aniyan elese, Ogo ni fun oruko Re O fun alare ni simi Ogo ni fun oruko Re 4. Nje n o royin na f’elese, Ogo ni fun oruko re Pe mo ti ri Olugbala Ogo ni fun oruko Re. 1 How sweet the name of Jesus sounds in a believer's ear! It soothes our sorrows, heals our wounds, and drives away our fear. 2 It makes the wounded spirit whole and calms the troubled breast; 'tis manna to the hungry soul, and to the weary, rest. 3 O Jesus, shepherd, guardian, friend, my Prophet, Priest, and King, my Lord, my Life, my Way, my End, accept the praise I bring. 4 How weak the effort of my heart, how cold my warmest thought; but when I see you as you are, I'll praise you as I ought. 5 Till then I would y...

Ọkan Arẹ, Ile kan n bẹ / O Weary Heart

  Author: William Henry Bellamy 1. Ọkan arẹ, ile kan n bẹ Jina rere s' aye ise; Ile t' ayida ko le de, Tani fe lo simi nibe? Egbe Duro.... roju duro, mase kun!: Duro, duro, sa roju, duro mase kun. 2. Bi wahala bo o mo 'le B' ipin re l' aiye ba buru, W' oke s' ile ibukun na, Sa roju duro, mase kun! 3. Bi egun ba wa l' ona re, Ranti ori t' a f' egun de; B' ibanuje bo okan re, O ti ri be f' Olugbala. 4. Ma sise lo, ma se ro pe A ko gb' adura edun re; Ojo isimi mbo kankan, Sa roju duro, mase kun. Source: Yoruba Baptist Hymnal #527 1. O weary heart, there is a Home, Beyond the reach of toil and care; A Home where changes never come: Who would not fain be resting there? Refrain Oh wait, meekly wait and murmur not! Oh wait, meekly wait and murmur not! Oh wait, Oh wait, Oh wait, Meekly wait and murmur not! 2. Yet when bow' down beneath the load By heav'n allow'd, thine earthly lot: Look up! Thou' It reach that blest abode: Wai...

Yin Oluwa Olodumare / Praise to the Lord, the Almighty

Author: Joachim Neander Yin Oluwa  Olodumare, Ọba Ẹlẹda Yin ọkan mi To r’on ni ‘lera ati ‘gbala rẹ Ẹyin t’ẹ gbọ,  Ẹ sunmọ tẹmpili Rẹ  Ẹ ba mi f’ayọ juba Rẹ. Yin Oluwa,  Ẹni t’O jọba lor’ ohun gbogbo  To dabobo,  To si gbe ọ ro labẹ iyẹ Rẹ  O ha ri pe  Gbogbo ohun to tọ lo ṣe  B’ O ti lana n’ipilẹṣẹ? Yin Oluwa,  Ẹni to da ọ t'ẹ̀rù, tìyanu  M'ara rẹ le  To gbe ọ ró nígbà tí o ṣubú  L'aini, ẹ̀dùn Ko ha fun ọ n'itura?  O f'ìyẹ́ anu Rẹ̀ bo ọ.   Yin Oluwa  To n bukun ’ṣẹ rẹ to si n gbeja rẹ;  L’otitọ 're ati anu rẹ n tọ ọ lẹyin  Ronu lọtun Ohun t’Oluwa le ṣe,  Ẹni to fifẹ yan ọ lọrẹ. Yin Oluwa,  Ẹni, n'gba t' awọn iji n jagun,  Ẹni, n'gba t' awọn 'ṣẹ̀dá  N runú, si n ja yi ọ ka,  Mu wọn dákẹ́  Sọ 'binu wọn d' alafia  To mú 'jì, omi dákẹ́ jẹ́.   Yin Oluwa, Ẹni, nigba okunkun ẹṣẹ n pọ sii,  Ẹni, nigba awọn eeyan buburu n gberu sii,  Tan mọle Rẹ̀, O...

Fi 'Bùkún F'Ólúwa, Ìwọ Ọkàn Mi / Bless the Lord Oh My Soul

  Songwriters: Jonas Myrin / Matt Redman Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀  Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ  Òrùn ti jí  Ojúmọ́ tún ti mọ́ Ó tó àkókò láti kọrin Rẹ síi Ohun tó lè dé Ohun tó lè wà níwájú mi Jẹ́ kí n máa kọrin t'ìrọ̀lẹ́ bá dé Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀  Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ  O pọ̀ nífẹ̀ẹ́  O lọ́ra láti bínú Oókọ Rẹ ńlá Onínúure ni Ọ́ Fun gbogbo oore Rẹ  N óò maa kọrin títí Ìdí ẹgbàrún Fọ́kàn mi láti wá Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀  Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ  Lọ́jọ́ náà 'Gb' okun mi bá ń ṣákì Tópin súnmọ́  T' àkókò mi dé Síbẹ̀ ọkàn mi Yóò kọrin àìlópin  Ọdún ẹgbàrún  Àti títí láí Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀  Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ Translated to Yoruba on 23/07/2024 by A...

Igbagbo Awọn Baba Wa/Faith of Our Fathers

1. Igbagbo awọn baba wa Ko bèru ida ati'na, Awa ọmọ wọn si l'ayo 'Gba t'a gbo 'royin 'gbagbo wọn! Igbagbo mimọ ti baba! A o j'olooto si ọ d'opin. 2. Igbagbo awọn baba wa,  A o jere gbogb’aye fun ọ,  Pelu otito Olorun, Awọn eeyan yoo d'om'nira:  Igbagbo mimọ ti baba! A o j'olooto si o d'opin. 3. Igbagbo awọn baba wa, A o fèrán orè at'ota, Ao si f'ifè nla rohin rè Ninu oro at'iṣe wa; Igbagbo mimo ti baba! A o j'olooto si ọ d'opin. Source: DLCM GHS#78 Faith of our fathers, living still In spite of dungeon, fire and sword, O how our hearts beat high with joy Whene’er we hear that glorious word! Faith of our fathers! holy faith! We will be true to thee till death! Our fathers, chained in prisons dark, Were still in heart and conscience free; And blest would be their children’s fate, If they, like them should die for thee: Faith of our fathers! holy faith! We will be true to thee till death! Faith of our fathers, we will...

Wọn Yoo Ṣe 'Ranti / Only Remembered

  Author: Horatius Bonar A o kọja lọ bi àwọn 'rawọ òórọ̀ T' ìmọ́lẹ̀ wọn n ran n'nu oorun ogo,  Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,  A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.  ÈGBÈ:  Wọn yoo ṣe 'ranti, wọn yoo ṣe 'ranti, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe,  Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,  A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.  A o ha kuro k' àwọn miran rọ́pò wa, Lati maa kore oko t' a ti gbìn?,  Bẹ́ẹ̀ l' àwọn òṣìṣẹ́ yoo fi 'ṣẹ́ sílẹ̀,   A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.  Kìkì òótọ́ ti a ba ti sọ láyé,  Pẹ̀lú 'rúgbìn t' a ti gbìn laye yii,  Yoo tẹ̀síwájú t' a ba ti gbàgbé wa,  Eso ikore at' on t' a ti ṣe.  'Gbà t' Olúwa yoo k' àwọn ayanfẹ Rẹ̀,  T'ao jere adé aláyọ̀ t' ó ntàn,  'Gba naa l' ao ranti àwọn olootọ Rẹ̀,  T' àárẹ̀ ti mu nip' on ti wọ́n ti ṣe. Source: Facebook  Fading away like the stars of t...