Posts

Showing posts from 2020

Alleluya! Kọrin sí Jésù! / Alleluia! Sing to Jesus!

Author: William Chatterton Dix (1866) Alleluya! Kọrin sí Jésù!  Tirẹ̀ lọ̀pá, Tirẹ̀ nìtẹ́;  Alleluya! Ó jagunmólú,  Tirẹ̀ nìkan ni ìsẹ́gun  Gbọ́! orin Sion' 'írọ̀rùn  Sán àrá bí ìgbì omi Jésù láti ilẹ̀ gbogbo Rà wá padà pẹ̀l' ẹ́jẹ̀ Rẹ̀.  Allelúyà! Kò fi wá sílẹ̀  Láti ṣọfọ bí òrukàn  Alleluya! O súnmọ́ wa  'Gbàgbọ́ kìí bèèrè pé báwo:  Bí 'kukù tilẹ̀ bojúu Rẹ̀  Lẹ́yìn ogójì ọjọ́  A óò ha gbàgbé ìlérí Rẹ̀,  'Mo wà pẹ̀lú yín dópin.' Alleluya! Àkàrà ángẹ́l',  'Wọ lóunjẹ àti wíwà wa Alleluya! Níhìn ẹlẹ́ṣẹ̀— Ń sá tọ́ Ọ́ ní ojúmọ́:  Olùbẹ̀bẹ̀, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́sẹ,  Olùràpadà, bẹ̀bẹ̀ fún mi,  Níb' orin àwọn ẹni mímọ́  Ti n la òkun krístálì jà.  Alleluya! Ọba àìkú,  Olúwa àwọn olúwa tiwa;  Alleluya! Ọmọ Mary,  Ayé nìtisẹ̀, ọ̀run nìtẹ́:  Ìwọ gba ikele kọjá  Olórí Àlùfáà wa; Àlùfáà àti ìrúbọ Ni àsè Yúkárístì.  Translated t...

Jesu, Ise Re L'o/Thy Works, Not Mine, O Christ

Author: George R. Prynne JESU, ise Re l'o Fi ayo s'okan mi, Nwon ni, o ti pari, Ki eru mi ko tan: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Jesu, ogbe Re l'o Le m'okan mi jina; N'nu 'ya Re ni mo ri Iwosan f'ese mi: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Agbelebu Tire L'o gbe eru ese, T'enikan ko le gbe, Lehin Om'Olorun: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Ki se iku t'emi L'o san irapada; Egbarun bi t'emi Ko to, o kere ju; Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Source: YBH 238 Thy works, not mine, O Christ, Speak gladness to this heart; They tell me all is done; They bid my fear depart. To whom, save Thee, who canst alone For sin atone, Lord, shall I flee?  Thy pains, not mine, O Christ, Upon the shameful tree, Have paid the law’s full price And purchased peace for me. To whom, save Thee, who canst alone For sin atone, Lord, shall I flee? Thy cross, not mine, O Christ,...

Jésù Onírẹ̀lẹ̀/Jesus, Meek and Gentle

Author: George R. Prynne Jesu Onirele, Omo Olorun: Alanu, Olufe, Gbo 'gbe omo Re. Fi ese wa jin wa Si da wa n' ide; Fo gbogbo orisa, Ti mbe l' okan wa. Fun wa ni omnira, F' ife s' okan wa; Fa wa Jesu mimo, S' ibugbe l' oke. To wa l' ona ajo, Si je ona wa; Ja okunkun aiye, S' imole orun. Jesu Onirele Omo Olorun, Alanu, olufe, Gbo gbe omo Re. Source: YBH #549 Jesus, meek and gentle, Son of God most High, Pitying, loving Savior, Hear Thy children’s cry. Pardon our offences, Loose our captive chains, Break down every idol Which our soul detains. Give us holy freedom, Fill our heart with grace; Lead us on our journey, Till we win the race. Jesus, meek and gentle, Son of God most high, Pitying, loving Savior, Hear Thy children’s cry. Source  

Gbayé Mi, Darí Mi o / Take My Life, Lead Me Lord

Author: R. Maines Rawls Gbayé mi, dar í mi o, Gbayé mi,  dar í mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Gbayé mi,  dar í mi o, Gbayé mi,  dar í mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Gbayé mi, kọ́ mi o, Gbayé mi, kọ́ mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Gbayé mi, kọ́ mi o, Gbayé mi, kọ́ mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Èmi rèé, rán mi o,  Èmi rèé, rán mi o,  Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ. Èmi rèé, rán mi o,  Èmi rèé, rán mi o,  Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ. Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (08/06/2020) Take my life, lead me Lord, Take my life, lead me Lord, Make my life useful to Thee. Take my life, lead me Lord, Take my life, lead me Lord, Make my life useful to Thee. Take my life, teach me Lord, Take my life, teach me Lord, Make my life useful to Thee. Take my life, teach me Lord, Take my life, teach me Lord, Make my life useful to Thee. Here am I, send...

Káàkiri Ayé / All Over The World world

Image
Káàkiri ayé Ẹ̀mí ń rábabà,   Káàkiri ayé báwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀;  Káàkiri ayé ìṣípayá ńlá kan wà  Ti ògo Olúwa, bi omi ti bo òkun.  Yíká ìjọ Rẹ̀ Ẹ̀mí ń rábabà,   Yíká ìjọ Rẹ̀ báwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀;  Yíká ìjọ Rẹ̀ ìṣípayá ńlá kan wà  Ti ògo Olúwa, bi omi ti bo òkun.  Ní ìhín yìí Ẹ̀mí ń rábabà,   Ní ìhín yìí báwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀;  Ní ìhín yìí ìṣípayá ńlá kan wà  Ti ògo Olúwa, bi omi ti bo òkun.  Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (02/06/2020) All over the world the Spirit is moving, All over the world as the prophet said it would be; All over the world there's a mighty revelation Of the glory of the Lord, as the waters cover the sea. All over His church God's Spirit is moving, All over His church as the prophet said it would be; All over His church there's a mighty revelation Of the glory of the Lord, as the waters cover the sea. Right here in this place...

Olurapada Kan Wa / There Is A Redeemer

Image
Olurapada Kan wa Jésù, Ọm' Ọlọ́run  Ọ̀dọ́-Àgùntàn, Messiah Ẹni Mímọ́  Jésù Olùràpadà mi Orúkọ tó j' orúkọ lọ  Ọ̀dọ́-Àgùntàn, Messiah Tí a pa f' ẹlẹ́ṣẹ̀  O ṣeun, Baba mi,  T'O f' Ọmọ Rẹ fún wa O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  Gba m' bá dúró logo  N o rí ojú Rẹ  Níbẹ̀, n o sin Ọba mi títí  Ni ibi mímọ́ yẹn.  O ṣeun, Baba mi,  T'O f' Ọmọ Rẹ fún wa O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  Olurapada Kan wa Jésù, Ọm' Ọlọ́run  Ọ̀dọ́-Àgùntàn, Messiah Ẹni Mímọ́  O ṣeun, Baba mi,  T'O f' Ọmọ Rẹ fún wa O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (28/05/2020) There is a redeemer Jesus, God's own Son Precious Lamb of God, Messiah Holy One Jesus my redeemer Name above all names Precious Lamb of God, Messiah Oh, for sinners slain Thank you, oh my fathe...

Ìyanu, Aláàánú Olùgbàlà / Wonderful, Merciful Saviour

Authors: Dawn Rodgers / Eric Wyse  Ìyanu, Olùgbàlà  aláàánú, Olùràpadà , ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n Ta ni 'bá rò p' Ọ̀d'àgùntàn Lè gbọkàn èèyàn là Àní, O gbọkàn ènìyàn là  Olùdámọ̀ràn, Olùtùnú, Olùpamọ́ Ẹ̀mí ta fẹ́ fà mọ́ra O fún wa n'rètí gbọkàn wa Ti rìnnà ṣáko lọ  Àní, a ti rìnnà ṣáko lọ.  Ègbè  Ìwọ l' Ẹni tí a yìn Ìwọ l' Ẹni tí a júbà  O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́ Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún Èdùmàrè, Baba àìlópin,  O fẹ́ wa ní òtítọ́  N'nú àìlera wa la wólẹ̀  Níwájú ìtẹ́ Rẹ  Àní, ní iwájú ìtẹ́ Rẹ  Ègbè  Ìwọ l' Ẹni tí a yìn Ìwọ l' Ẹni tí a júbà  O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́ Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (30/04/2020) Wonderful, merciful Saviour Precious Redeemer and Friend Who would've thought t...

Ọkàn Mi Mọ̀ ’Yẹn Dájú / And That My Soul Knows Very Well

Authors: Darlene Zschech / Russell Fragar O tàn ’mọ́lẹ̀ ojú Rẹ sára mi Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú O gbé mi ga, mo mọ́, mo bọ́ Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú Egbe ’Gbòkè ṣídìí n ó dúró Nípa ’gbára ọwọ́ Rẹ̀ Àti n'n' ààjìn ọ̀kan Rẹ̀, n ó wà Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú. Ayọ̀, okun, mo ń rí l’ójúmọ́  Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú ’Dáríjì, ’rètí jẹ́ tèmi Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú. Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (28/04/2020) You make Your face to shine on me Now my soul knows very well You lift me up an' I'm cleansed and free Now my soul knows very well Refrain When  mountains fall, I'll stand By the power of Your hand And in Your heart of hearts, I'll dwell That my soul knows very well Joy and strength each day I find That my soul knows very well Forgiveness, hope, I know is mine That my soul knows very well Songwriters: Darlene Joyce Zschech / Russell Fragar And That My Soul Knows Very Well lyrics © Capit...

Ki N Mo Nipa Jesu Sii / More About Jesus

Author: E. E. Hewitt (1887 ) Mo fe mo nipa Jesu sii, F'or' ofe Re h' elomiran; Ki n le ri 'gbala kikun Re, Ki n mo 'fe 'ni to ku fun mi. Egbe: Ki n mo nipa Jesu sii, Ki n mo nipa Jesu sii; Ki n le ri 'gbala kikun Re, Ki n mo 'fe 'ni to ku fun mi N o ko nipa Jesu sii, Ki n da 'fe Re mimo mo si i; K' Em' Olorun j'oluko mi, Fi ona ti Kristi han mi. Ki n mo Jesu si n'oro Re, Ki n ma b'Oluwa mi soro; Ki n si gbo 'ro Re lokokan, So 'ro 'tito Re di t'emi. Ki n mo Jesu l 'ori 'te Re, Pel' oro gbogbo Ogo Re; Mo bi'joba Re ti n po si, Bibo Re Oba 'lafia Source: YBH #618 More about Jesus  would I know, More of His grace to others show; More of His saving fulness see, More of His love who died for me. Refrain: More, more about Jesus, More, more about Jesus; More of His saving fulness see, More of His love who died for me. More about Jesus let me lea...

Yíyẹ L'Ọdaguntan / Worthy Is The Lamb

Image
Author: Darlene Zschech Translated by Ayobami Temitope Kehinde on April 12, 2020 O ṣeun f'ágbèlébù Olúwa  O ṣeun fún ’díyelé t'O san O gbẹ́ṣẹ̀, ’tìjú mi rù Nifẹ̀ l'O wa Pẹl' or'ọfẹ ìyanu O ṣeun fun ’fẹ́ yii, Olúwa  O ṣeun f' ọwọ́ ta gun niṣo  O wẹ mi n'nú iṣan Rẹ,  Wàyíí mo mọ̀  ’Dariji, ’tẹwogba Rẹ.  Egbe: Yíyẹ l'Ọdaguntan T'O joko lor' itẹ́  A de Ọ lade ọpọlọpọ O ń jọba n'iṣẹgun Gbigbega ni Ọ Jésù, Ọm' Ọlọrun Ààyò ọ̀run ti a kan mọ́gi  Yíyẹ l'Ọdaguntan Yíyẹ l'Ọdaguntan Thank you for the cross, Lord Thank you for the price You paid Bearing all my sin and shame In love You came And gave amazing grace Thank you for this love, Lord Thank you for the nail pierced hands Washed me in Your cleansing flow Now all I know Your forgiveness and embrace Refrain: Worthy is the Lamb Seated on the throne Crown You now with many crowns You reign victorious ...

'Bukun Ni Fun Ohun / Blest Be The Tie That Binds

Author: John Fawcett, pub. 1782 'Bukun ni fun ohun, T' o de wa po n'nu 'fe; Idapo awon olufe, Dabi ijo t' orun. Niwaju 'te Baba, Li awa ngbadura; Okan n' ireti at' eru, Ati ni itunu. Awa mb' ara wa pin Ninu wahala wa; Awa si mb' ara wa sokun Ninu 'banuje wa. Nigbat' a ba pinya, Inu wa a baje; Sibe okan wa y'o j' okan N' ireti ipade. Source: YBH #318 Blest be the tie that binds Our hearts in Christian love; The fellowship of kindred minds Is like to that above. Before our Father’s throne, We pour our ardent prayers; Our fears, our hopes, our aims are one— Our comforts and our cares. We share our mutual woes; Our mutual burdens bear; And often for each other flows The sympathizing tear. When we asunder part, It gives us inward pain; But we shall still be joined in heart, And hope to meet again. From sorrow, toil, and pain, And sin we shall be free; And perfect lo...

Alafia, Ni Aye Ese Yi / Peace, Perfect Peace

Image
Author: Edward H. Bickersteth, Jr., 1875 Alafia, ni aye ese yi Eje Jesu n wipe, "Alafia!" Alafia, ninu opo lala? Lati se ife Jesu ni 'simi. Alafia, n'nu igbi 'banuje? L' aiya Jesu n' idakeroro wa. Alafia, n'nu ijiya lile? Ikaanu Jesu mu 'bale okan wa. Alafia, gb' ara wa wa l' ajo? N' ipamo Jesu, iberu ko si. Alafia, b' a ko tile m' ola? Sugbon a mo pe Jesu wa lailai. Alafia, nigb' akoko iku? Olugbala wa ti segun iku. O to: 'jakadi aye fere pin, Jesu y' o pe wa s' orun alafia. Source: Stanzas 1-3 & 5-8 from YBH #259 Stanza 4 translated by Ayobami Temitope Kehinde (07/04/2020) Peace, perfect peace, in this dark world of sin? The blood of Jesus whispers peace within. Peace, perfect peace, by thronging duties pressed? To do the will of Jesus, this is rest. Peace, perfect peace, with sorrows surging round? On Jesus’ bosom naught but calm is found. Peace, perfect peace,...

A O Ha Pade Leti Odo / Shall We Gather at the River

Author: Robert Lowry A o ha pade l' eti odo, T' ese angeli ti te, 'T o mo gara bi kristali, Leba ite Olorun? A o pade l' eti odo, Odo didan, odo didan na, Pel' awon mimo leb' odo, T' o nsan leba ite na? L' eti bebe odo na yi, Pel' Olus'-agutan wa, A o ma rin, a o sin, B' a ti ntele 'pase Re. K' a to de odo didan na, A o s' eru wa kale; Jesu yio gba eru ese Awon ti yio de l' ade. Nje leba odo tutu na, Ao r' oju Olugbala; Emi wa ki o pinya mo, Yio korin ogo Re. Source: YBH #487 Shall we gather at the river, Where bright angel feet have trod; With its crystal tide forever Flowing by the throne of God? Refrain: Yes, we'll gather at the river, The beautiful, the beautiful river; Gather with the saints at the river That flows by the throne of God. On the margin of the river, Washing up its silver spray, We will walk and worship ever, All the happy golden day. Ere we reach the shi...

Ore wo la ni bi Jesu

William Cowper, 1731-1800 Ore wo l’ani bi Jesu, ti o ru banuje wa! Anfani wo lo po bayi lati ma gbadura si! Alafia pupo l’a nsonu, a si ti je rora po, Tori a ko fi gbogbo nkan s’adura niwaju re. Idanwo ha wa fun wa bi? A ha nni wahala bi? A ko gbodo so ’reti nu; sa gbadura si Oluwa. Ko s’oloto orebi re ti ole ba wa daro, Jesu ti mo ailera wa; sa gbadura s’Oluwa. Eru ha nwo wa l’orun bi, aniyan ha po fun wa? Olugbala je abo wa, sa gbadura s’Oluwa. Awon ore ha sa o ti? Sa gbadura s’Oluwa. Yo gbe o soke lapa re, Iwo yo si ri itunu. What a friend we have in Jesus All our sins and grief to bear What privilege to carry everything to God in prayer  What a peace we often forfeit  What a needless pain we bear All because we do not carry everything to God in prayer.  Have we trials and tempations? Is there trouble anywhere? We should never be discouraged  Take it to the Lord in prayer.  Can we find a friend so faithful ? Who...

Ìyanilẹ́nu! Ìjọnilójú! / How Marvellous! How Wonderful!

Image
Author: Charles Hutchinson Gabriel Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Ní ìyanu ni mo dúró Níwájú Jésù Nasaret' Mo sì ń wòye b' Ó ti fẹ́ mi tó Ẹlẹ́ṣẹ̀ ta dá lẹbi Ìyanilẹ́nu! Ìjọnilójú! Ni orin mi yó ma jẹ̀ Ìyanilẹ́nu! Ìjọnilójú! Ìfẹ́ Olùgbàlà mi.  Fún mi, nín' ọgbà ló gbàdúrà "Jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ kó ṣẹ." Ko sun tori irora Rẹ Ṣùgbọ́n O sunro ẹjẹ fun mi.  Tẹduntẹdun l'angẹli woo, Wọn wa la'taye 'mọlẹ Lati gbé E ró 'nu ' banuje To ru fokan mi lalẹ yẹn Ó mẹ́ṣẹ̀ àti 'bànújẹ́ mi, Ò fi wọ́n ṣe Tirẹ̀ Ó gbẹ́rù wúwo dé Kalfari Ó da jìyà, Ó dá kú. 'Gbà pẹ̀lú àwọn táa rà padà  Mo rójú Rẹ̀ níkẹhìn  N ò fayọ̀ kọrin títí ayé Orin ìfẹ́ Rẹ̀ fún mi.  I stand amazed in the presence Of Jesus the Nazarene, And wonder how He could love me, A sinner condemned, unclean Refrain How marvellous! How wonderful! And my song shall ever be: How marvelous! ...