Posts

Si Ọ Olutunu Ọrun/To Thee, O Comforter Divine

Author: Frances Ridley Havergal 1. Si O, Olutunu orun, Fun ore at’ agbara Re, A nko Alleluya. 2. Si O, ife Eni t’ O wa Ninu majemu Olorun, A nko Alleluya. 3. Si O, ohun Eni ti npe Asako kuro n’nu ese, A nko Alleluya. 4. Si O, agbara Eni ti O n weni mo, t’ O nwo ni san, A nko Alleluya. 5. Si O, Eni t'ododo Re Han nipa 'leri to je tiwa, A nko Alleluia. 6. Si O, Oluko at’ Ore, Amona wa toto d’ opin, A nko Alleluya. 7. Si O, Eni ti Kristi ran, Ade o'n gbongbo ebun Re, A nko Alleluya. 8. Si O, Eni t’ O je okan Pelu Baba ati Omo, A nko Alleluya. Amin. Source: Iwe Orin Mimo #278 (Verse 5 adjusted by me) 1. To Thee, O Comforter divine, For all Thy grace and power benign, Sing we Alleluia! 2. To Thee, Whose faithful love had place In God's great covenant of grace, Sing we Alleluia! 3. To Thee, Whose faithful voice doth win The wandering from the ways of sin, Sing we Alleluia! 4. To Thee, Whose faithful power doth heal, Enlighten, sanctify, and seal, Sing we Alleluia! 5. To Thee...

Ki N Le Rin Sun Mọ Ọ Sii / Just A Closer Walk With Thee

Author: Unknown   Mo ṣaarẹ, O lagbara Jesu gba mi lọw’ ẹṣẹ N o nitẹlọrun n’wọn ’gba Mo ba Ọ rin, jẹ ki n le ba Ọ rin Egbe: Ki n le rin sun mọ Ọ sii Jesu, f’ ẹ̀bẹ̀ yii fun mi Ki n ba Ọ rin lojumọ  Je ko ṣẹ, Oluwa, je ko ṣẹ Laye 'ṣẹ́, ìkẹkùn yii Tí m' ba kùnà ta lo kan?  Ta ló ń bá mi gbẹ́rù mi Kò sí o, Oluwa, Ìwọ ni.  ’Gbà ’yé àíléra mi pin Tí ’gba mi láyé dópin Tọ́jú mi títí délé  ’Jọba Rẹ̀, àní ìjọba Rẹ Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 20/05/2024 I am weak but Thou art strong; Jesus, keep me from all wrong; I'll be satisfied as long As I walk, let me walk close to Thee. Refrain: Just a closer walk with Thee, Grant it, Jesus, is my plea, Daily walking close to Thee, Let it be, dear Lord, let it be. Thro' this world of toil and snares, If I falter, Lord, who cares? Who with me my burden shares? None but Thee, dear Lord, none but Thee. [Refrain] When my feeble life is o'er, Time for me will be no more; Gui...

Ọkàn, O Ha Ń Ṣàárẹ̀ / O Soul, Are You Weary

Author: Lemmel, Helen Howarth Ọkàn, o ha ń ṣàárẹ̀, o ń dààmú Òkùn ṣú kò sí ìmọ́lẹ̀ 'Mọ́lẹ̀ wà t'o bá w'Olùgbàlà 'Yè lọ́pọ̀lọpọ̀ àt' ọ̀fẹ́  Kọ ojú rẹ sí Jésù  Wò ojú ìyanu Rẹ̀  Àwọn nǹkan ayé yóò si di bàìbàì  N'nú 'mọ́lẹ̀ ògo, or' ọ̀fẹ́ Rẹ̀ Láti 'kú lọ s' íyè àínìpẹ̀kun O kọjá, a sì tẹ̀le lọ Lórí i wa ẹ̀ṣẹ̀ kò lágbára  Àwá ju aṣẹ́gun lọ  Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ k'yo' kùnà, Ó lérí Gbà á gbọ́, yóò dára fún ọ  Sì lọ sí ayé tí ń kú lọ  Sọ ti ìgbàlà pípé' Rẹ̀  Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 12th April, 2024 O soul, are you weary and troubled? No light in the darkness you see? There’s light for a look at the Saviour, And life more abundant and free! Turn your eyes upon Jesus, Look full in His wonderful face, And the things of earth will grow strangely dim, In the light of His glory and grace. Through death into life everlasting He passed, and we follow Him there; O’er us sin no more h...

MO FERAN RE JESU / MY JESUS I LOVE THEE

Authors: James H. Duffel (1862); William R. Featherston (1862) Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi Mo feran re Jesu ju t'ateyin wa  Mo feran Re ni iye ati ni iku  N o ma yin Oruko Re gba m' ba wa laye  Gba temi mi ba n lo tojo mi n buse  Sibe n o feran Re tit'ojo aye mi  Ile ewa wonni bo ti dara to  N o dapo mawon mimo lati maa yin o Pelu ade wura lem'o ma yin O N o feran Re Jesu laye ati lorun  Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi  N o feran Re ju tateyin lo. Source: Orin Duru My Jesus, I love thee, I know thou art mine; For thee all the follies of sin I resign; My gracious Redeemer, my Saviour art thou; If ever I loved thee, my Jesus, ‘tis now. I love thee because thou hast first loved me And purchased my pardon on Calvary’s tree; I love thee for wearing the thorns on thy brow; If ever I love...

Jesu to Lewa Ju/Fairest Lord Jesus

Author: Unknown Jesu to lẹwa ju, adari ẹda gbogbo Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan N o mọ riri Rẹ, n o bu ọla fun Ọ 'Wọ, ogo, ayọ, ade ọkan mi. Didara lawọn ọdan, sibẹ igi 'gbo dara ju Ta wọ pel' ogo igba 'ruwe Jesu dara julọ, Jesu mọ́ ju wọ́n lọ O mọkan 'banujẹ kọrin Didara ni oorun, sibẹ oṣupa dara ju, Ati awọn irawọ ti n tan Jesu mọlẹ ju wọn, Jesu tan ju wọn lọ Ju gbogbo angẹli ni ọrun Olugbala arẹwa! Oluwa ilẹ gbogbo, Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ Eeyan! Ogo ati ọla, iyin ati' juba, Ko jẹ Tirẹ titi lailai. Translated by Ayọbami Temitọpẹ Kẹhinde on 3rd April, 2024 Fairest Lord Jesus, ruler of all nature O thou of God and man the Son Thee will I cherish, Thee will I honour Thou, my soul's glory, joy, and crown Fair are the meadows, fairer still the woodlands Robed in the blooming garb of spring Jesus is fairer, Jesus is purer Who makes the woeful heart to sing Fair is the sunshine, fairer still the moonlight And all t...

Asiwaju Ogun Orun/ The Champion of the Hosts Above

Image
Author: Nathaniel Bassey Mo wa' waju Oluw' Oba mi Eni to femi Re fun mi N'o gb' asia ookọ Rẹ soke Títi gbogb' ayé yóò ké pè É Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo A dohun po m' akorin orun 'Yin Olugbala, Oba wa A pee n' Emmanueli wa O ra wa lowo 'ku, ese Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 22/01/2024 I come before my Lord and King The one who gave His life for me I'll raise the banner of his name Until the nations call on Him The champion of the hosts above And captain of my destiny In You alone I make my boast You reign alone as Lord of all We sing as one with heaven's choir The p...

O Fa Mi Yọ Ninu Erọfọ/He Brought Me Out Of The Miry Clay

Image
Author: Henry J. Zelley Author (refrain): H. L. Gilmour Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Okan mi gbọgbẹ labẹ 'binu  Jehofa, Ninu ọgbun ti ẹṣẹ mi ti mi si; Mo ke p' Oluwa lati 'nu ẹrọfọ, T'O fi 'yọnu fa mi yọ sọjọ wura Egbe: O fa mi yọ ninu ẹrọfọ  O gbẹsẹ mi sori apata O f'orin sin' ọkan mi loni Orin iyin, alleluia  O gbe mi lori Apata ẹgbẹ Rẹ, Iṣisẹ mi mulẹ, n o duro nibi; Ko sewu iṣubu 'gba mo wa nihin, Ṣugbọn n o duro titi n o fi gbade. O fun mi l'orin, orin   iyin tuntun; L'owurọ, l'alẹ n o maa kọọ titi ni; Ọkan mi fo fayọ, mo dominira; N o yin Olurapada mi t'O gba mi. N o kọrin aanu iyanu Rẹ si mi, N o yin tit' aye yoo fi mọ p'O dara; N o kọrin 'gbala nile lẹyin odi, K'ọpọ le gbotitọ Rẹ k'ọn si gbaa gbọ. N o royin ọgbun ati okunkun rẹ, N o yin Baba mi to gbọ adura mi; N o kọrin titun, orin ayọ t'ifẹ, N o si gberin pẹl' awọn mimọ loke. Translated by Ayobami Temitope Kehinde November 3, 2023. ...

FUN ẸWA ILE AYE /FOR THE BEAUTY OF THE EARTH

Image
Credit: Pexels.com Author: Folliott Sandford Pierpoint (1864) Fun ẹwa ile aye,  Fun ogo oju ọrun, Fun ifẹ to yi wa ka  Lati 'gba t'a ti bi wa; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun.  Fun iyanu wakati  Ọjọọjọ at' alaalẹ, Oke, 'lẹ, igi, ododo Orun, oṣupa 'rawọ; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayo eti, oju, Fun idunnu okan wa Fun irepo adiitu T'ori, riri o'n gbigbo Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayọ ifẹ eeyan,  Ọmọ 'ya, obi, ọmọ,  Ọrẹ aye, ọrẹ oke,  Fun gbogbo ero tutu; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun 'jọ Rẹ t'o n gbe ọwọ  Mimọ soke titi lai Nibi gbogbo t'o n rubọ,  Irubọ ifẹ pipe; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 16/02/2022 For the beauty of the earth  For the glory of the skies,  For the love which from our birth  Over and around us lies. Christ our Lord, to Thee we raise,  This our hymn of grat...

E Yin! E Yin!/Praise Him! Praise Him!

Author: Fanny J. Crosby (1869) E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'orin aye, e kede 'fe nla Re! E kii! E kii! Eyin angeli ologo; F'ipa at'ola f'oruko Re mimo! B'Olus'aguntan, Jesu yoo s'awon 'mo Re, Lapa Re lo n gbe won lojojumo. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! Fun ese wa, o jiya, o si ku. Apata wa, ireti 'gbala ailopin, E kii! E kii! Jesu t'a kan mo'gi. E ro iyin Re! O ru ibanuje wa; Ife nla, to yanu, to jin, to ki. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'iro hosanna ko gba orun kan! Jesu Olugbala joba titi aye; E dee lade! Woli, Al'fa, Oba! Krist' n pada bo! Lori aye n'isegun, Agbara, ogo - t'Oluwa nii se. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (06/06/2023) Praise Him! Praise Him!  Jesus, our blessed Redeemer!...

Ilu Wura /Golden City

Laipe idamu yin yoo pin Owo anu yoo gbe yin ga E o ri iran kedere Ilekun si ile miran Egbe A o pade ni ilu wura Ni Jerusalem' tuntun Gbogbo 'rora, omije wa ko ni si mọ́ A o dúró pẹ̀lú ogun ọrún A o ke mímọ̀ l'Oluwa  A o sin, a o juba Rẹ títí ayé.  Baba yoo ki wa ku abo Igbasoke lo sile Iduro wa ti de opin A wole ni ite Re Ka ma rii, agbara okunkun Tabi iku tabi iye Ko si oun to le ya Kuro n'nu 'fe Oluwa Afara Mimo, mimo l'Odo Aguntan (Mimo, mimo l'Odo Aguntan) (Mimo ni O) Mimo, mimo l'Odo Aguntan Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 23/05/2021 Soon your trials will be over Offered up by mercy's hand A better view than where you're standing A doorway to another land The sweetest welcome from the Father Gathered up and carried home We are past this time of waiting Come let us bow before Your throne Refrain We will meet in the Golden City in the New Jerusalem All our pain and all our tears will be...

Onibu Ore /Giver of All

  Author: Christopher Wordsworth Oluwa ọrún oun aye Wo n'iyin at’ope ye fun Bawo la ba ti fe O to! Onibu ore Orun ti n ran at’afefe Gbogbo eweko nso ’fe Re Wo lo nmu irugbin dara Onibu ore Fun ara lile wa gbogbo Fun gbogbo ibukun aye Awa yin O, a si dupe Onibu ore O ko du wa ni omo re O fi fun aye ese wa Pelu Re l'ofe l'O n fun wa L' ohun gbogbo. O fun wa l'Emi Mimo Re Emi iye at’agbara O ro’jo ekun ’bukun Re Le wa lori   Fun idariji ese wa, Ati fun ireti orun, Ki lohun ta ba fi fun O, Onibu ore?   Owo ti a n na, ofo ni, Sugbon eyi ta fi fun O O je isura tit’ aye Onibu ore Ohun ta bun O, Oluwa Wo o san le pada fun wa Layo la ta O lore Onibu ore. Ni odo Re l’a ti san wa, Olorun Olodumare, Je ka le ba O gbe titi Onibu ore. Amin. Source: CAC YORUBA&ENGLISH HYMNAL #662 O Lord of heaven and earth and sea, To Thee all praise and glory be; How shall we show our love to Thee, Giver of all? The golden sunshine, vernal air, Sweet flowers and fruits, Thy love declare Wher...

Alleluya! Kọrin sí Jésù! / Alleluia! Sing to Jesus!

Author: William Chatterton Dix (1866) Alleluya! Kọrin sí Jésù!  Tirẹ̀ lọ̀pá, Tirẹ̀ nìtẹ́;  Alleluya! Ó jagunmólú,  Tirẹ̀ nìkan ni ìsẹ́gun  Gbọ́! orin Sion' 'írọ̀rùn  Sán àrá bí ìgbì omi Jésù láti ilẹ̀ gbogbo Rà wá padà pẹ̀l' ẹ́jẹ̀ Rẹ̀.  Allelúyà! Kò fi wá sílẹ̀  Láti ṣọfọ bí òrukàn  Alleluya! O súnmọ́ wa  'Gbàgbọ́ kìí bèèrè pé báwo:  Bí 'kukù tilẹ̀ bojúu Rẹ̀  Lẹ́yìn ogójì ọjọ́  A óò ha gbàgbé ìlérí Rẹ̀,  'Mo wà pẹ̀lú yín dópin.' Alleluya! Àkàrà ángẹ́l',  'Wọ lóunjẹ àti wíwà wa Alleluya! Níhìn ẹlẹ́ṣẹ̀— Ń sá tọ́ Ọ́ ní ojúmọ́:  Olùbẹ̀bẹ̀, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́sẹ,  Olùràpadà, bẹ̀bẹ̀ fún mi,  Níb' orin àwọn ẹni mímọ́  Ti n la òkun krístálì jà.  Alleluya! Ọba àìkú,  Olúwa àwọn olúwa tiwa;  Alleluya! Ọmọ Mary,  Ayé nìtisẹ̀, ọ̀run nìtẹ́:  Ìwọ gba ikele kọjá  Olórí Àlùfáà wa; Àlùfáà àti ìrúbọ Ni àsè Yúkárístì.  Translated t...

Jesu, Ise Re L'o/Thy Works, Not Mine, O Christ

Author: George R. Prynne JESU, ise Re l'o Fi ayo s'okan mi, Nwon ni, o ti pari, Ki eru mi ko tan: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Jesu, ogbe Re l'o Le m'okan mi jina; N'nu 'ya Re ni mo ri Iwosan f'ese mi: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Agbelebu Tire L'o gbe eru ese, T'enikan ko le gbe, Lehin Om'Olorun: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Ki se iku t'emi L'o san irapada; Egbarun bi t'emi Ko to, o kere ju; Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Source: YBH 238 Thy works, not mine, O Christ, Speak gladness to this heart; They tell me all is done; They bid my fear depart. To whom, save Thee, who canst alone For sin atone, Lord, shall I flee?  Thy pains, not mine, O Christ, Upon the shameful tree, Have paid the law’s full price And purchased peace for me. To whom, save Thee, who canst alone For sin atone, Lord, shall I flee? Thy cross, not mine, O Christ,...

Jésù Onírẹ̀lẹ̀/Jesus, Meek and Gentle

Author: George R. Prynne Jesu Onirele, Omo Olorun: Alanu, Olufe, Gbo 'gbe omo Re. Fi ese wa jin wa Si da wa n' ide; Fo gbogbo orisa, Ti mbe l' okan wa. Fun wa ni omnira, F' ife s' okan wa; Fa wa Jesu mimo, S' ibugbe l' oke. To wa l' ona ajo, Si je ona wa; Ja okunkun aiye, S' imole orun. Jesu Onirele Omo Olorun, Alanu, olufe, Gbo gbe omo Re. Source: YBH #549 Jesus, meek and gentle, Son of God most High, Pitying, loving Savior, Hear Thy children’s cry. Pardon our offences, Loose our captive chains, Break down every idol Which our soul detains. Give us holy freedom, Fill our heart with grace; Lead us on our journey, Till we win the race. Jesus, meek and gentle, Son of God most high, Pitying, loving Savior, Hear Thy children’s cry. Source  

Gbayé Mi, Darí Mi o / Take My Life, Lead Me Lord

Author: R. Maines Rawls Gbayé mi, dar í mi o, Gbayé mi,  dar í mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Gbayé mi,  dar í mi o, Gbayé mi,  dar í mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Gbayé mi, kọ́ mi o, Gbayé mi, kọ́ mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Gbayé mi, kọ́ mi o, Gbayé mi, kọ́ mi o, Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ.  Èmi rèé, rán mi o,  Èmi rèé, rán mi o,  Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ. Èmi rèé, rán mi o,  Èmi rèé, rán mi o,  Jẹ́ kí n lè wúlò fún Ọ. Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (08/06/2020) Take my life, lead me Lord, Take my life, lead me Lord, Make my life useful to Thee. Take my life, lead me Lord, Take my life, lead me Lord, Make my life useful to Thee. Take my life, teach me Lord, Take my life, teach me Lord, Make my life useful to Thee. Take my life, teach me Lord, Take my life, teach me Lord, Make my life useful to Thee. Here am I, send...

Káàkiri Ayé / All Over The World world

Image
Káàkiri ayé Ẹ̀mí ń rábabà,   Káàkiri ayé báwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀;  Káàkiri ayé ìṣípayá ńlá kan wà  Ti ògo Olúwa, bi omi ti bo òkun.  Yíká ìjọ Rẹ̀ Ẹ̀mí ń rábabà,   Yíká ìjọ Rẹ̀ báwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀;  Yíká ìjọ Rẹ̀ ìṣípayá ńlá kan wà  Ti ògo Olúwa, bi omi ti bo òkun.  Ní ìhín yìí Ẹ̀mí ń rábabà,   Ní ìhín yìí báwọn wòlíì ti sọ tẹ́lẹ̀;  Ní ìhín yìí ìṣípayá ńlá kan wà  Ti ògo Olúwa, bi omi ti bo òkun.  Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (02/06/2020) All over the world the Spirit is moving, All over the world as the prophet said it would be; All over the world there's a mighty revelation Of the glory of the Lord, as the waters cover the sea. All over His church God's Spirit is moving, All over His church as the prophet said it would be; All over His church there's a mighty revelation Of the glory of the Lord, as the waters cover the sea. Right here in this place...

Olurapada Kan Wa / There Is A Redeemer

Image
Olurapada Kan wa Jésù, Ọm' Ọlọ́run  Ọ̀dọ́-Àgùntàn, Messiah Ẹni Mímọ́  Jésù Olùràpadà mi Orúkọ tó j' orúkọ lọ  Ọ̀dọ́-Àgùntàn, Messiah Tí a pa f' ẹlẹ́ṣẹ̀  O ṣeun, Baba mi,  T'O f' Ọmọ Rẹ fún wa O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  Gba m' bá dúró logo  N o rí ojú Rẹ  Níbẹ̀, n o sin Ọba mi títí  Ni ibi mímọ́ yẹn.  O ṣeun, Baba mi,  T'O f' Ọmọ Rẹ fún wa O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  Olurapada Kan wa Jésù, Ọm' Ọlọ́run  Ọ̀dọ́-Àgùntàn, Messiah Ẹni Mímọ́  O ṣeun, Baba mi,  T'O f' Ọmọ Rẹ fún wa O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  O fún wa l’ Ẹ̀mí Rẹ titi  Iṣẹ́ Rẹ laye yóò parí  Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (28/05/2020) There is a redeemer Jesus, God's own Son Precious Lamb of God, Messiah Holy One Jesus my redeemer Name above all names Precious Lamb of God, Messiah Oh, for sinners slain Thank you, oh my fathe...

Ìyanu, Aláàánú Olùgbàlà / Wonderful, Merciful Saviour

Authors: Dawn Rodgers / Eric Wyse  Ìyanu, Olùgbàlà  aláàánú, Olùràpadà , ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n Ta ni 'bá rò p' Ọ̀d'àgùntàn Lè gbọkàn èèyàn là Àní, O gbọkàn ènìyàn là  Olùdámọ̀ràn, Olùtùnú, Olùpamọ́ Ẹ̀mí ta fẹ́ fà mọ́ra O fún wa n'rètí gbọkàn wa Ti rìnnà ṣáko lọ  Àní, a ti rìnnà ṣáko lọ.  Ègbè  Ìwọ l' Ẹni tí a yìn Ìwọ l' Ẹni tí a júbà  O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́ Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún Èdùmàrè, Baba àìlópin,  O fẹ́ wa ní òtítọ́  N'nú àìlera wa la wólẹ̀  Níwájú ìtẹ́ Rẹ  Àní, ní iwájú ìtẹ́ Rẹ  Ègbè  Ìwọ l' Ẹni tí a yìn Ìwọ l' Ẹni tí a júbà  O fun wa n'wòsàn àt' or'ọ̀fẹ́ Tọ́kàn wa ń pòǹgbẹ fún Àní, tí ọkàn wa ń pòǹgbẹ fún Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (30/04/2020) Wonderful, merciful Saviour Precious Redeemer and Friend Who would've thought t...

Ọkàn Mi Mọ̀ ’Yẹn Dájú / And That My Soul Knows Very Well

Authors: Darlene Zschech / Russell Fragar O tàn ’mọ́lẹ̀ ojú Rẹ sára mi Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú O gbé mi ga, mo mọ́, mo bọ́ Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú Egbe ’Gbòkè ṣídìí n ó dúró Nípa ’gbára ọwọ́ Rẹ̀ Àti n'n' ààjìn ọ̀kan Rẹ̀, n ó wà Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú. Ayọ̀, okun, mo ń rí l’ójúmọ́  Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú ’Dáríjì, ’rètí jẹ́ tèmi Ọkàn mi mọ̀ ’yẹn dájú. Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (28/04/2020) You make Your face to shine on me Now my soul knows very well You lift me up an' I'm cleansed and free Now my soul knows very well Refrain When  mountains fall, I'll stand By the power of Your hand And in Your heart of hearts, I'll dwell That my soul knows very well Joy and strength each day I find That my soul knows very well Forgiveness, hope, I know is mine That my soul knows very well Songwriters: Darlene Joyce Zschech / Russell Fragar And That My Soul Knows Very Well lyrics © Capit...

Ki N Mo Nipa Jesu Sii / More About Jesus

Author: E. E. Hewitt (1887 ) Mo fe mo nipa Jesu sii, F'or' ofe Re h' elomiran; Ki n le ri 'gbala kikun Re, Ki n mo 'fe 'ni to ku fun mi. Egbe: Ki n mo nipa Jesu sii, Ki n mo nipa Jesu sii; Ki n le ri 'gbala kikun Re, Ki n mo 'fe 'ni to ku fun mi N o ko nipa Jesu sii, Ki n da 'fe Re mimo mo si i; K' Em' Olorun j'oluko mi, Fi ona ti Kristi han mi. Ki n mo Jesu si n'oro Re, Ki n ma b'Oluwa mi soro; Ki n si gbo 'ro Re lokokan, So 'ro 'tito Re di t'emi. Ki n mo Jesu l 'ori 'te Re, Pel' oro gbogbo Ogo Re; Mo bi'joba Re ti n po si, Bibo Re Oba 'lafia Source: YBH #618 More about Jesus  would I know, More of His grace to others show; More of His saving fulness see, More of His love who died for me. Refrain: More, more about Jesus, More, more about Jesus; More of His saving fulness see, More of His love who died for me. More about Jesus let me lea...