Posts

'Bi 'Sadi Nla L'Olorun Wa / A Mighty Fortress is Our God

Author: Martin Luther (1529) 'Bi'sadi nla l'Ọlọrun wa, Odi wa ti ko le yẹ;  Olùrànlọ́wọ́ n'nu igbi Idanwo to yi wa ka  'Tori ọta 'gba nni, Tun fẹ ṣe wa n'ibi;  Agbara rẹ si pọ, Pẹlu ikorira,  Ko s'iru rẹ ni aye yi. A ko gbẹkẹl' agbara wa,  Tori yo ja wa kulẹ  Ti ko ba si pe Ẹni naa, Ti Ọlọrun yan fun wa  O fẹ m'Ẹni naa bi?  Jesu Kristi ni iṣe  Oluwa Ologun,  Ẹni ayeraye,  Yoo si ṣẹgun ni dandan. B'ẹmi aimọ ni gbogb'aye,  N halẹ lati bo wa mọlẹ; A ki o bẹru 'tor'Ọlọrun  Fẹ ṣẹgun nípasẹ̀ wa;  Ọm' alade okunkun,  Ẹ̀rù rẹ̀ ko ba wa A o bori 'runu rẹ Iparun rẹ daju Ọr' Ọlọ́run yoo bii ṣubu Ọrọ yẹn ju agbara aye lọ,  Ṣíọ̀ sí wọn, o wa titi, Ẹ̀mí at' awọn ẹ̀bùn Rẹ̀  Jẹ tiwa nipasẹ Jesu. Ẹrù, ará lè lọ, At' ara kiku yìí  Won le pa ara yìí: Oot' Ọlọ́run sì wà Ìjọba Rẹ̀ wà títí láí.  Source: Hymnaro #703 (Some adjustments made in the translation by me, Ayobami Temitope Kehinde) ...

B’ORUKO JESU TI DUN TO / HOW SWEET THE NAME OF JESUS SOUNDS

Author: John Newton 1. B’oruko Jesu ti dun to, Ogo ni fun Oruko Re o tan banuje at’ogbe Ogo ni fun oruko Re Ogo f’oko Re, ogo f’oko Re Ogo f’oruko Oluwa Ogo f’oko Re, ogo f’oko Re Ogo f’oruko Oluwa 2. O wo okan to gb’ogbe san Ogo ni fun oruko Re Ounje ni f’okan t’ebi npa Ogo ni fun oruko Re 3. O tan aniyan elese, Ogo ni fun oruko Re O fun alare ni simi Ogo ni fun oruko Re 4. Nje n o royin na f’elese, Ogo ni fun oruko re Pe mo ti ri Olugbala Ogo ni fun oruko Re. 1 How sweet the name of Jesus sounds in a believer's ear! It soothes our sorrows, heals our wounds, and drives away our fear. 2 It makes the wounded spirit whole and calms the troubled breast; 'tis manna to the hungry soul, and to the weary, rest. 3 O Jesus, shepherd, guardian, friend, my Prophet, Priest, and King, my Lord, my Life, my Way, my End, accept the praise I bring. 4 How weak the effort of my heart, how cold my warmest thought; but when I see you as you are, I'll praise you as I ought. 5 Till then I would y...

Ọkan Arẹ, Ile kan n bẹ / O Weary Heart

  Author: William Henry Bellamy 1. Ọkan arẹ, ile kan n bẹ Jina rere s' aye ise; Ile t' ayida ko le de, Tani fe lo simi nibe? Egbe Duro.... roju duro, mase kun!: Duro, duro, sa roju, duro mase kun. 2. Bi wahala bo o mo 'le B' ipin re l' aiye ba buru, W' oke s' ile ibukun na, Sa roju duro, mase kun! 3. Bi egun ba wa l' ona re, Ranti ori t' a f' egun de; B' ibanuje bo okan re, O ti ri be f' Olugbala. 4. Ma sise lo, ma se ro pe A ko gb' adura edun re; Ojo isimi mbo kankan, Sa roju duro, mase kun. Source: Yoruba Baptist Hymnal #527 1. O weary heart, there is a Home, Beyond the reach of toil and care; A Home where changes never come: Who would not fain be resting there? Refrain Oh wait, meekly wait and murmur not! Oh wait, meekly wait and murmur not! Oh wait, Oh wait, Oh wait, Meekly wait and murmur not! 2. Yet when bow' down beneath the load By heav'n allow'd, thine earthly lot: Look up! Thou' It reach that blest abode: Wai...

Yin Oluwa Olodumare / Praise to the Lord, the Almighty

Author: Joachim Neander Yin Oluwa  Olodumare, Ọba Ẹlẹda Yin ọkan mi To r’on ni ‘lera ati ‘gbala rẹ Ẹyin t’ẹ gbọ,  Ẹ sunmọ tẹmpili Rẹ  Ẹ ba mi f’ayọ juba Rẹ. Yin Oluwa,  Ẹni t’O jọba lor’ ohun gbogbo  To dabobo,  To si gbe ọ ro labẹ iyẹ Rẹ  O ha ri pe  Gbogbo ohun to tọ lo ṣe  B’ O ti lana n’ipilẹṣẹ? Yin Oluwa,  Ẹni to da ọ t'ẹ̀rù, tìyanu  M'ara rẹ le  To gbe ọ ró nígbà tí o ṣubú  L'aini, ẹ̀dùn Ko ha fun ọ n'itura?  O f'ìyẹ́ anu Rẹ̀ bo ọ.   Yin Oluwa  To n bukun ’ṣẹ rẹ to si n gbeja rẹ;  L’otitọ 're ati anu rẹ n tọ ọ lẹyin  Ronu lọtun  Ohun t’Oluwa le ṣe,  Ẹni to fifẹ yan ọ lọrẹ. Yin Oluwa,  Ẹni, n'gba t' awọn iji n jagun,  Ẹni, n'gba t' awọn 'ṣẹ̀dá  N runú, si n ja yi ọ ka,  Mu wọn dákẹ́  Sọ 'binu wọn d' alafia  To mú 'jì, omi dákẹ́ jẹ́.   Yin Oluwa, Ẹni, nigba okunkun ẹṣẹ n pọ sii,  Ẹni, nigba awọn eeyan buburu n gberu sii,  Tan mọle ...

Fi 'Bùkún F'Ólúwa, Ìwọ Ọkàn Mi / Bless the Lord Oh My Soul

  Songwriters: Jonas Myrin / Matt Redman Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀  Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ  Òrùn ti jí  Ojúmọ́ tún ti mọ́ Ó tó àkókò láti kọrin Rẹ síi Ohun tó lè dé Ohun tó lè wà níwájú mi Jẹ́ kí n máa kọrin t'ìrọ̀lẹ́ bá dé Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀  Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ  O pọ̀ nífẹ̀ẹ́  O lọ́ra láti bínú Oókọ Rẹ ńlá Onínúure ni Ọ́ Fun gbogbo oore Rẹ  N óò maa kọrin títí Ìdí ẹgbàrún Fọ́kàn mi láti wá Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀  Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ  Lọ́jọ́ náà 'Gb' okun mi bá ń ṣákì Tópin súnmọ́  T' àkókò mi dé Síbẹ̀ ọkàn mi Yóò kọrin àìlópin  Ọdún ẹgbàrún  Àti títí láí Fi 'bùkún f'Ólúwa, ìwọ ọkàn mi Júbà f'orúkọ Rẹ̀  Kọrin ju tàtẹ̀hìnwá, ọkàn mi N óò júbà f'órúkọ Rẹ Translated to Yoruba on 23/07/2024 by A...

Igbagbo Awọn Baba Wa/Faith of Our Fathers

1. Igbagbo awọn baba wa Ko bèru ida ati'na, Awa ọmọ wọn si l'ayo 'Gba t'a gbo 'royin 'gbagbo wọn! Igbagbo mimọ ti baba! A o j'olooto si ọ d'opin. 2. Igbagbo awọn baba wa,  A o jere gbogb’aye fun ọ,  Pelu otito Olorun, Awọn eeyan yoo d'om'nira:  Igbagbo mimọ ti baba! A o j'olooto si o d'opin. 3. Igbagbo awọn baba wa, A o fèrán orè at'ota, Ao si f'ifè nla rohin rè Ninu oro at'iṣe wa; Igbagbo mimo ti baba! A o j'olooto si ọ d'opin. Source: DLCM GHS#78 Faith of our fathers, living still In spite of dungeon, fire and sword, O how our hearts beat high with joy Whene’er we hear that glorious word! Faith of our fathers! holy faith! We will be true to thee till death! Our fathers, chained in prisons dark, Were still in heart and conscience free; And blest would be their children’s fate, If they, like them should die for thee: Faith of our fathers! holy faith! We will be true to thee till death! Faith of our fathers, we will...

Wọn Yoo Ṣe 'Ranti / Only Remembered

  Author: Horatius Bonar A o kọja lọ bi àwọn 'rawọ òórọ̀ T' ìmọ́lẹ̀ wọn n ran n'nu oorun ogo,  Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,  A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.  ÈGBÈ:  Wọn yoo ṣe 'ranti, wọn yoo ṣe 'ranti, A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe,  Bẹ́ẹ̀ l' a o lọ kúrò l' aye ati 'ṣẹ rẹ̀,  A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.  A o ha kuro k' àwọn miran rọ́pò wa, Lati maa kore oko t' a ti gbìn?,  Bẹ́ẹ̀ l' àwọn òṣìṣẹ́ yoo fi 'ṣẹ́ sílẹ̀,   A o maa ranti wa nip' on t' a ti ṣe.  Kìkì òótọ́ ti a ba ti sọ láyé,  Pẹ̀lú 'rúgbìn t' a ti gbìn laye yii,  Yoo tẹ̀síwájú t' a ba ti gbàgbé wa,  Eso ikore at' on t' a ti ṣe.  'Gbà t' Olúwa yoo k' àwọn ayanfẹ Rẹ̀,  T'ao jere adé aláyọ̀ t' ó ntàn,  'Gba naa l' ao ranti àwọn olootọ Rẹ̀,  T' àárẹ̀ ti mu nip' on ti wọ́n ti ṣe. Source: Facebook  Fading away like the stars of t...

Si Ọ Olutunu Ọrun/To Thee, O Comforter Divine

Author: Frances Ridley Havergal 1. Si O, Olutunu orun, Fun ore at’ agbara Re, A nko Alleluya. 2. Si O, ife enit’ o wa Ninu majemu Olorun, A nko Alleluya. 3. Si O, Ohun Eniti npe Asako kuro n’nu ese, A nko Alleluya. 4. Si O, agbara Eniti O n weni mo, t’ o nwo ni san, A nko Alleluya. 5. Si O, ododo Eniti Gbogbo ’leri Re je tiwa, A nko Alleluia. 6. Si O, Oluko at’ Ore, Amona wa toto d’ opin, A nko Alleluya. 7. Si O, Eniti Kristi ran, Ade o'n gbongbo ebun Re, A nko Alleluya. 8. Si O, Enit’ o je okan Pelu Baba ati Omo, A nko Alleluya. Amin. Source: Iwe Orin Mimo #278 1. To Thee, O Comforter divine, For all Thy grace and power benign, Sing we Alleluia! 2. To Thee, Whose faithful love had place In God's great covenant of grace, Sing we Alleluia! 3. To Thee, Whose faithful voice doth win The wandering from the ways of sin, Sing we Alleluia! 4. To Thee, Whose faithful power doth heal, Enlighten, sanctify, and seal, Sing we Alleluia! 5. To Thee, Whose faithful truth is shown By every pr...

Ki N Le Rin Sun Mọ Ọ Sii / Just A Closer Walk With Thee

Author: Unknown   Mo ṣaarẹ, O lagbara Jesu gba mi lọw’ ẹṣẹ N o nitẹlọrun n’wọn ’gba Mo ba Ọ rin, jẹ ki n le ba Ọ rin Egbe: Ki n le rin sun mọ Ọ sii Jesu, f’ ẹ̀bẹ̀ yii fun mi Ki n ba Ọ rin lojumọ  Je ko ṣẹ, Oluwa, je ko ṣẹ Laye 'ṣẹ́, ìkẹkùn yii Tí m' ba kùnà ta lo kan?  Ta ló ń bá mi gbẹ́rù mi Kò sí o, Oluwa, Ìwọ ni.  ’Gbà ’yé àíléra mi pin Tí ’gba mi láyé dópin Tọ́jú mi títí délé  ’Jọba Rẹ̀, àní ìjọba Rẹ Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 20/05/2024 I am weak but Thou art strong; Jesus, keep me from all wrong; I'll be satisfied as long As I walk, let me walk close to Thee. Refrain: Just a closer walk with Thee, Grant it, Jesus, is my plea, Daily walking close to Thee, Let it be, dear Lord, let it be. Thro' this world of toil and snares, If I falter, Lord, who cares? Who with me my burden shares? None but Thee, dear Lord, none but Thee. [Refrain] When my feeble life is o'er, Time for me will be no more; Gui...

Ọkàn, O Ha Ń Ṣàárẹ̀ / O Soul, Are You Weary

Author: Lemmel, Helen Howarth Ọkàn, o ha ń ṣàárẹ̀, o ń dààmú Òkùn ṣú kò sí ìmọ́lẹ̀ 'Mọ́lẹ̀ wà t'o bá w'Olùgbàlà 'Yè lọ́pọ̀lọpọ̀ àt' ọ̀fẹ́  Kọ ojú rẹ sí Jésù  Wò ojú ìyanu Rẹ̀  Àwọn nǹkan ayé yóò si di bàìbàì  N'nú 'mọ́lẹ̀ ògo, or' ọ̀fẹ́ Rẹ̀ Láti 'kú lọ s' íyè àínìpẹ̀kun O kọjá, a sì tẹ̀le lọ Lórí i wa ẹ̀ṣẹ̀ kò lágbára  Àwá ju aṣẹ́gun lọ  Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ k'yo' kùnà, Ó lérí Gbà á gbọ́, yóò dára fún ọ  Sì lọ sí ayé tí ń kú lọ  Sọ ti ìgbàlà pípé' Rẹ̀  Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 12th April, 2024 O soul, are you weary and troubled? No light in the darkness you see? There’s light for a look at the Saviour, And life more abundant and free! Turn your eyes upon Jesus, Look full in His wonderful face, And the things of earth will grow strangely dim, In the light of His glory and grace. Through death into life everlasting He passed, and we follow Him there; O’er us sin no more h...

MO FERAN RE JESU / MY JESUS I LOVE THEE

Authors: James H. Duffel (1862); William R. Featherston (1862) Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi Mo feran re Jesu ju t'ateyin wa  Mo feran Re ni iye ati ni iku  N o ma yin Oruko Re gba m' ba wa laye  Gba temi mi ba n lo tojo mi n buse  Sibe n o feran Re tit'ojo aye mi  Ile ewa wonni bo ti dara to  N o dapo mawon mimo lati maa yin o Pelu ade wura lem'o ma yin O N o feran Re Jesu laye ati lorun  Mo feran Re Jesu mo mo p'O fe mi  Nitori Re n o ko ese mi sile  Olugbala owon Oludande mi  N o feran Re ju tateyin lo. Source: Orin Duru My Jesus, I love thee, I know thou art mine; For thee all the follies of sin I resign; My gracious Redeemer, my Saviour art thou; If ever I loved thee, my Jesus, ‘tis now. I love thee because thou hast first loved me And purchased my pardon on Calvary’s tree; I love thee for wearing the thorns on thy brow; If ever I love...

Jesu to Lewa Ju/ Fairest Lord Jesus

Author: Unknown Jesu to lẹwa ju, adari ẹda gbogbo Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan N o mọ riri Rẹ, n o bu ọla fun Ọ 'Wọ, ogo, ayọ, ade ọkan mi. Didara lawọn ọdan, sibẹ igi 'gbo dara ju Ta wọ pel' ogo igba 'ruwe Jesu dara julọ, Jesu funfun julọ O mọkan 'banujẹ kọrin Didara ni oorun, sibẹ oṣupa dara ju, Ati awọn irawọ ti n tan Jesu mọlẹ ju wọn, Jesu tan ju wọn lọ Ju gbogbo angẹli ni ọrun Olugbala arẹwa, Oluwa ilẹ gbogbo, Ọm' Ọlọrun at' Ọmọ eeyan! Ogo ati ọla, iyin ati' juba, Ko jẹ Tirẹ titi lailai. Translated by Ayọbami Temitọpẹ Kẹhinde on 3rd April, 2024 Fairest Lord Jesus, ruler of all nature O thou of God and man the Son Thee will I cherish, Thee will I honour Thou, my soul's glory, joy, and crown Fair are the meadows, fairer still the woodlands Robed in the blooming garb of spring Jesus is fairer, Jesus is purer Who makes the woeful heart to sing Fair is the sunshine, fairer still the moonlight And all the ...

Asiwaju Ogun Orun/ The Champion of the Hosts Above

Image
Author: Nathaniel Bassey Mo wa' waju Oluw' Oba mi Eni to femi Re fun mi N'o gb' asia ookọ Rẹ soke Títi gbogb' ayé yóò ké pè É Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo A dohun po m' akorin orun 'Yin Olugbala, Oba wa A pee n' Emmanueli wa O ra wa lowo 'ku, ese Asiwaju ogun orun Balogun ayanmo aye mi N'nu Re nikan ni mo n sogo 'Wo nikan loba, Oluwa gbogbo Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Amin, amin, amin, alleluia Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 22/01/2024 I come before my Lord and King The one who gave His life for me I'll raise the banner of his name Until the nations call on Him The champion of the hosts above And captain of my destiny In You alone I make my boast You reign alone as Lord of all We sing as one with heaven's choir The p...

O Fa Mi Yọ Ninu Erọfọ/He Brought Me Out Of The Miry Clay

Author: Henry J. Zelley Author (refrain): H. L. Gilmour Yoruba Translator: Ayobami Temitope Kehinde Okan mi gbọgbẹ labẹ 'binu  Jehofa, Ninu ọgbun ti ẹṣẹ mi ti mi si; Mo ke p' Oluwa lati 'nu ẹrọfọ, T'O fi 'yọnu fa mi yọ sọjọ wura Egbe: O fa mi yọ ninu ẹrọfọ  O gbẹsẹ mi sori apata O f'orin sin' ọkan mi loni Orin iyin, alleluia  O gbe mi lori Apata ẹgbẹ Rẹ, Iṣisẹ mi mulẹ, n o duro nibi; Ko sewu iṣubu 'gba mo wa nihin, Ṣugbọn n o duro titi n o fi gbade. O fun mi l'orin, orin   iyin tuntun; L'owurọ, l'alẹ n o maa kọọ titi ni; Ọkan mi fo fayọ, mo dominira; N o yin Olurapada mi t'O gba mi. N o kọrin aanu iyanu Rẹ si mi, N o yin tit' aye yoo fi mọ p'O dara; N o kọrin 'gbala nile lẹyin odi, K'ọpọ le gbotitọ Rẹ k'ọn si gbaa gbọ. N o royin ọgbun ati okunkun rẹ, N o yin Baba mi to gbọ adura mi; N o kọrin titun, orin ayọ t'ifẹ, N o si gberin pẹl' awọn mimọ loke. Translated by Ayobami Temitope Kehinde November 3, 2023. ...

FUN ẸWA ILE AYE /FOR THE BEAUTY OF THE EARTH

Image
Credit: Pexels.com Author: Folliott Sandford Pierpoint (1864) Fun ẹwa ile aye,  Fun ogo oju ọrun, Fun ifẹ to yi wa ka  Lati 'gba t'a ti bi wa; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun.  Fun iyanu wakati  Ọjọọjọ at' alaalẹ, Oke, 'lẹ, igi, ododo Orun, oṣupa 'rawọ; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayo eti, oju, Fun idunnu okan wa Fun irepo adiitu T'ori, riri o'n gbigbo Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun ayọ ifẹ eeyan,  Ọmọ 'ya, obi, ọmọ,  Ọrẹ aye, ọrẹ oke,  Fun gbogbo ero tutu; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Fun 'jọ Rẹ t'o n gbe ọwọ  Mimọ soke titi lai Nibi gbogbo t'o n rubọ,  Irubọ ifẹ pipe; Krist' Oluwa, Iwọ la fi Orin iyin wa yii fun. Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 16/02/2022 For the beauty of the earth  For the glory of the skies,  For the love which from our birth  Over and around us lies. Christ our Lord, to Thee we raise,  This our hymn of grat...

E Yin! E Yin!/Praise Him! Praise Him!

Author: Fanny J. Crosby (1869) E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'orin aye, e kede 'fe nla Re! E kii! E kii! Eyin angeli ologo; F'ipa at'ola f'oruko Re mimo! B'Olus'aguntan, Jesu yoo s'awon 'mo Re, Lapa Re lo n gbe won lojojumo. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! Fun ese wa, o jiya, o si ku. Apata wa, ireti 'gbala ailopin, E kii! E kii! Jesu t'a kan mo'gi. E ro iyin Re! O ru ibanuje wa; Ife nla, to yanu, to jin, to ki. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! E yin! E yin! Jesu Olurapada wa! K'iro hosanna ko gba orun kan! Jesu Olugbala joba titi aye; E dee lade! Woli, Al'fa, Oba! Krist' n pada bo! Lori aye n'isegun, Agbara, ogo - t'Oluwa nii se. E yin! E yin! E so tiyi titobi Re; E yin! E yin! Titi lorin ayo! Translated to Yoruba by Ayobami Temitope Kehinde (06/06/2023) Praise Him! Praise Him!  Jesus, our blessed Redeemer!...

Ilu Wura /Golden City

Laipe idamu yin yoo pin Owo anu yoo gbe yin ga E o ri iran kedere Ilekun si ile miran Egbe A o pade ni ilu wura Ni Jerusalem' tuntun Gbogbo 'rora, omije wa ko ni si mọ́ A o dúró pẹ̀lú ogun ọrún A o ke mímọ̀ l'Oluwa  A o sin, a o juba Rẹ títí ayé.  Baba yoo ki wa ku abo Igbasoke lo sile Iduro wa ti de opin A wole ni ite Re Ka ma rii, agbara okunkun Tabi iku tabi iye Ko si oun to le ya Kuro n'nu 'fe Oluwa Afara Mimo, mimo l'Odo Aguntan (Mimo, mimo l'Odo Aguntan) (Mimo ni O) Mimo, mimo l'Odo Aguntan Translated by Ayobami Temitope Kehinde on 23/05/2021 Soon your trials will be over Offered up by mercy's hand A better view than where you're standing A doorway to another land The sweetest welcome from the Father Gathered up and carried home We are past this time of waiting Come let us bow before Your throne Refrain We will meet in the Golden City in the New Jerusalem All our pain and all our tears will be...

Onibu Ore /Giver of All

  Author: Christopher Wordsworth Oluwa ọrún oun aye Wo n'iyin at’ope ye fun Bawo la ba ti fe O to! Onibu ore Orun ti n ran at’afefe Gbogbo eweko nso ’fe Re Wo lo nmu irugbin dara Onibu ore Fun ara lile wa gbogbo Fun gbogbo ibukun aye Awa yin O, a si dupe Onibu ore O ko du wa ni omo re O fi fun aye ese wa Pelu Re l'ofe l'O n fun wa L' ohun gbogbo. O fun wa l'Emi Mimo Re Emi iye at’agbara O ro’jo ekun ’bukun Re Le wa lori   Fun idariji ese wa, Ati fun ireti orun, Ki lohun ta ba fi fun O, Onibu ore?   Owo ti a n na, ofo ni, Sugbon eyi ta fi fun O O je isura tit’ aye Onibu ore Ohun ta bun O, Oluwa Wo o san le pada fun wa Layo la ta O lore Onibu ore. Ni odo Re l’a ti san wa, Olorun Olodumare, Je ka le ba O gbe titi Onibu ore. Amin. Source: CAC YORUBA&ENGLISH HYMNAL #662 O Lord of heaven and earth and sea, To Thee all praise and glory be; How shall we show our love to Thee, Giver of all? The golden sunshine, vernal air, Sweet flowers and fruits, Thy love declare Wher...

Alleluya! Kọrin sí Jésù! / Alleluia! Sing to Jesus!

Author: William Chatterton Dix (1866) Alleluya! Kọrin sí Jésù!  Tirẹ̀ lọ̀pá, Tirẹ̀ nìtẹ́;  Alleluya! Ó jagunmólú,  Tirẹ̀ nìkan ni ìsẹ́gun  Gbọ́! orin Sion' 'írọ̀rùn  Sán àrá bí ìgbì omi Jésù láti ilẹ̀ gbogbo Rà wá padà pẹ̀l' ẹ́jẹ̀ Rẹ̀.  Allelúyà! Kò fi wá sílẹ̀  Láti ṣọfọ bí òrukàn  Alleluya! O súnmọ́ wa  'Gbàgbọ́ kìí bèèrè pé báwo:  Bí 'kukù tilẹ̀ bojúu Rẹ̀  Lẹ́yìn ogójì ọjọ́  A óò ha gbàgbé ìlérí Rẹ̀,  'Mo wà pẹ̀lú yín dópin.' Alleluya! Àkàrà ángẹ́l',  'Wọ lóunjẹ àti wíwà wa Alleluya! Níhìn ẹlẹ́ṣẹ̀— Ń sá tọ́ Ọ́ ní ojúmọ́:  Olùbẹ̀bẹ̀, Ọ̀rẹ́ ẹlẹ́sẹ,  Olùràpadà, bẹ̀bẹ̀ fún mi,  Níb' orin àwọn ẹni mímọ́  Ti n la òkun krístálì jà.  Alleluya! Ọba àìkú,  Olúwa àwọn olúwa tiwa;  Alleluya! Ọmọ Mary,  Ayé nìtisẹ̀, ọ̀run nìtẹ́:  Ìwọ gba ikele kọjá  Olórí Àlùfáà wa; Àlùfáà àti ìrúbọ Ni àsè Yúkárístì.  Translated t...

Jesu, Ise Re L'o/Thy Works, Not Mine, O Christ

Author: George R. Prynne JESU, ise Re l'o Fi ayo s'okan mi, Nwon ni, o ti pari, Ki eru mi ko tan: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Jesu, ogbe Re l'o Le m'okan mi jina; N'nu 'ya Re ni mo ri Iwosan f'ese mi: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Agbelebu Tire L'o gbe eru ese, T'enikan ko le gbe, Lehin Om'Olorun: Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Ki se iku t'emi L'o san irapada; Egbarun bi t'emi Ko to, o kere ju; Odo tani emi 'ba lo, Lehin Iwo t'O s'etutu? Source: YBH 238 Thy works, not mine, O Christ, Speak gladness to this heart; They tell me all is done; They bid my fear depart. To whom, save Thee, who canst alone For sin atone, Lord, shall I flee?  Thy pains, not mine, O Christ, Upon the shameful tree, Have paid the law’s full price And purchased peace for me. To whom, save Thee, who canst alone For sin atone, Lord, shall I flee? Thy cross, not mine, O Christ,...